2. Nigbati awọn enia buburu, ani awọn ọta mi ati awọn abinuku mi sunmọ mi lati jẹ ẹran ara mi, nwọn kọsẹ, nwọn si ṣubu.
3. Bi ogun tilẹ dótì mi, aiya mi kì yio fò: bi ogun tilẹ dide si mi, ninu eyi li ọkàn mi yio le.
4. Ohun kan li emi ntọrọ li ọdọ Oluwa, on na li emi o ma wakiri: ki emi ki o le ma gbe inu ile Oluwa li ọjọ aiye mi gbogbo, ki emi ki o le ma wò ẹwà Oluwa, ki emi ki o si ma fi inu-didùn wò tempili rẹ̀.
5. Nitori pe ni igba ipọnju on o pa mi mọ́ ninu agọ rẹ̀: ni ibi ìkọkọ àgọ́ rẹ̀ ni yio pa mi mọ́; yio si gbé mi soke kà ori apata.