O. Daf 147:17-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. O dà omi didì rẹ̀ bi òkele; tali o le duro niwaju otutu rẹ̀.

18. O rán ọ̀rọ rẹ̀ jade, o si mu wọn yọ́; o mu afẹfẹ rẹ̀ fẹ, omi si nṣàn.

19. O fi ọ̀rọ rẹ̀ hàn fun Jakobu, aṣẹ rẹ̀ ati idajọ rẹ̀ fun Israeli.

20. Kò ba orilẹ-ède kan ṣe bẹ̃ ri; bi o si ṣe ti idajọ rẹ̀ ni, nwọn kò mọ̀ wọn. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.

O. Daf 147