O. Daf 145:6-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Enia o si ma sọ̀rọ agbara iṣẹ rẹ ti o li ẹ̀ru; emi o si ma ròhin titobi rẹ.

7. Nwọn o ma sọ̀rọ iranti ore rẹ pupọ̀-pupọ̀, nwọn o si ma kọrin ododo rẹ.

8. Olore-ọfẹ li Oluwa, o kún fun ãnu; o lọra lati binu, o si li ãnu pupọ̀.

9. Oluwa ṣeun fun ẹni gbogbo; iyọ́nu rẹ̀ si mbẹ lori iṣẹ rẹ̀ gbogbo.

10. Oluwa, gbogbo iṣẹ rẹ ni yio ma yìn ọ; awọn enia mimọ́ rẹ yio si ma fi ibukún fun ọ.

11. Nwọn o ma sọ̀rọ ogo ijọba rẹ, nwọn o si ma sọ̀rọ agbara rẹ:

12. Lati mu iṣẹ agbara rẹ̀ di mimọ̀ fun awọn ọmọ enia, ati ọla-nla ijọba rẹ̀ ti o logo,

O. Daf 145