1. OLUWA ni mo fi ohùn mi kigbe pè; ohùn mi ni mo fi mbẹ̀bẹ mi si Oluwa.
2. Emi tú aroye mi silẹ niwaju rẹ̀; emi fi iṣẹ́ mi hàn niwaju rẹ̀.
3. Nigbati ọkàn mi rẹ̀wẹsi ninu mi, nigbana ni iwọ mọ̀ ipa-ọ̀na mi. Li ọ̀na ti emi nrìn ni nwọn dẹkùn silẹ fun mi nikọ̀kọ.