7. Nibo li emi o gbe lọ kuro lọwọ ẹmi rẹ? tabi nibo li emi o sárè kuro niwaju rẹ?
8. Bi emi ba gòke lọ si ọrun, iwọ wà nibẹ: bi emi ba si tẹ́ ẹni mi ni ipò okú, kiyesi i, iwọ wà nibẹ.
9. Emi iba mu iyẹ-apa owurọ, ki emi si lọ joko niha opin okun;
10. Ani nibẹ na li ọwọ rẹ yio fà mi, ọwọ ọtún rẹ yio si dì mi mu.
11. Bi mo ba wipe, Njẹ ki òkunkun ki o bò mi mọlẹ; ki imọlẹ ki o di oru yi mi ka.
12. Nitõtọ òkunkun kì iṣu lọdọ rẹ; ṣugbọn oru tàn imọlẹ bi ọsan: ati òkunkun ati ọsan, mejeji bakanna ni fun ọ.
13. Nitori iwọ li o dá ọkàn mi: iwọ li o bò mi mọlẹ ni inu iya mi.