O. Daf 139:21-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Oluwa, njẹ emi kò korira awọn ti o korira rẹ? njẹ inu mi kò ha si bajẹ si awọn ti o dide si ọ?

22. Emi korira wọn li àkotan: emi kà wọn si ọta mi.

23. Ọlọrun, wadi mi, ki o si mọ̀ aiya mi: dán mi wò, ki o si mọ̀ ìro-inu mi:

24. Ki o si wò bi ipa-ọ̀na buburu kan ba wà ninu mi, ki o si fi ẹsẹ mi le ọ̀na ainipẹkun.

O. Daf 139