O. Daf 130:1-4 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LATI inu ibu wá li emi kepe ọ, Oluwa.

2. Oluwa, gbohùn mi, jẹ ki eti rẹ ki o tẹ́ silẹ si ohùn ẹ̀bẹ mi.

3. Oluwa, ibaṣepe iwọ a mã sami ẹ̀ṣẹ, Oluwa, tani iba duro?

4. Nitori idariji wà lọdọ rẹ, ki a le ma bẹ̀ru rẹ.

O. Daf 130