O. Daf 122:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. INU mi dùn nigbati nwọn wi fun mi pe, Ẹ jẹ ki a lọ si ile Oluwa.

2. Ẹsẹ wa yio duro ni ẹnu-bode rẹ, iwọ Jerusalemu.

3. Jerusalemu, iwọ ti a kọ́ bi ilu ti o fi ara mọra pọ̀ ṣọkan.

4. Nibiti awọn ẹ̀ya ima gòke lọ, awọn ẹ̀ya Oluwa, ẹri fun Israeli, lati ma dupẹ fun orukọ Oluwa.

5. Nitori ibẹ li a gbé itẹ́ idajọ kalẹ, awọn itẹ́ ile Dafidi.

6. Gbadura fun alafia Jerusalemu: awọn ti o fẹ ọ yio ṣe rere.

O. Daf 122