O. Daf 119:64-72 Yorùbá Bibeli (YCE)

64. Oluwa, aiye kún fun ãnu rẹ: kọ́ mi ni ilana rẹ.

65. Iwọ ti nṣe rere fun iranṣẹ rẹ Oluwa, gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ.

66. Kọ́ mi ni ìwa ati ìmọ̀ rere; nitori ti mo gbà aṣẹ rẹ gbọ́.

67. Ki a to pọ́n mi loju emi ti ṣina: ṣugbọn nisisiyi emi ti pa ọ̀rọ rẹ mọ́.

68. Iwọ ṣeun iwọ si nṣe rere; kọ́ mi ni ilana rẹ.

69. Awọn agberaga ti hùmọ eke si mi: ṣugbọn emi o pa ẹkọ́ rẹ mọ́ tinutinu mi gbogbo.

70. Aiya wọn sebọ bi ọrá; ṣugbọn emi o ṣe inu-didùn ninu ofin rẹ.

71. O dara fun mi ti a pọ́n mi loju; ki emi ki o le kọ́ ilana rẹ.

72. Ofin ẹnu rẹ dara fun mi jù ẹgbẹgbẹrun wura ati fadaka lọ.

O. Daf 119