O. Daf 119:59-63 Yorùbá Bibeli (YCE)

59. Emi rò ọ̀na mi, mo si yi ẹsẹ mi pada si ẹri rẹ.

60. Emi yara, emi kò si lọra lati pa ofin rẹ mọ́.

61. Okùn awọn enia buburu ti yi mi ka: ṣugbọn emi kò gbagbe ofin rẹ.

62. Lãrin ọganjọ emi o dide lati dupẹ fun ọ nitori ododo idajọ rẹ.

63. Ẹgbẹ gbogbo awọn ti o bẹ̀ru rẹ li emi, ati ti awọn ti npa ẹkọ́ rẹ mọ́.

O. Daf 119