O. Daf 119:44-47 Yorùbá Bibeli (YCE)

44. Bẹ̃li emi o ma pa ofin rẹ mọ́ patapata titi lai ati lailai.

45. Bẹ̃li emi o ma rìn ni alafia; nitori ti mo wá ẹkọ́ rẹ.

46. Emi o si ma sọ̀rọ ẹri rẹ niwaju awọn ọba, emi kì yio si tiju.

47. Emi o si ma ṣe inu-didùn ninu aṣẹ rẹ, ti emi ti fẹ.

O. Daf 119