O. Daf 119:151-155 Yorùbá Bibeli (YCE)

151. Oluwa, iwọ wà ni itosi: otitọ si ni gbogbo aṣẹ rẹ.

152. Lati inu ẹri rẹ, emi ti mọ̀ nigba atijọ pe, iwọ ti fi idi wọn mulẹ lailai.

153. Wò ipọnju mi, ki o si gbà mi: nitori ti emi kò gbagbe ofin rẹ.

154. Gbà ẹjọ mi rò, ki o rà mi pada: sọ mi di ãye nipa ọ̀rọ rẹ.

155. Igbala jina si awọn enia buburu: nitori ti nwọn kò wá ilana rẹ.

O. Daf 119