O. Daf 119:15-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Emi o ma ṣe àṣaro ninu ẹkọ́ rẹ emi o si ma juba ọ̀na rẹ.

16. Emi o ma ṣe inu-didùn ninu ilana rẹ: emi kì yio gbagbe ọ̀rọ rẹ.

17. Fi ọ̀pọlọpọ ba iranṣẹ rẹ ṣe, ki emi ki o le wà lãye, ki emi ki o le ma pa ọ̀rọ rẹ mọ́.

18. Là mi li oju, ki emi ki o le ma wò ohun iyanu wọnni lati inu ofin rẹ.

O. Daf 119