O. Daf 119:134-137 Yorùbá Bibeli (YCE)

134. Gbà mi lọwọ inilara enia; bẹ̃li emi o si ma pa ẹkọ́ rẹ mọ́.

135. Ṣe oju rẹ ki o mọlẹ si iranṣẹ rẹ lara; ki o si kọ mi ni ilana rẹ.

136. Odò omi ṣàn silẹ li oju mi nitori nwọn kò pa ofin rẹ mọ́.

137. Olododo ni iwọ, Oluwa, ati diduro-ṣinṣin ni idajọ rẹ.

O. Daf 119