O. Daf 119:127-136 Yorùbá Bibeli (YCE)

127. Nitorina emi fẹ aṣẹ rẹ jù wura, ani, jù wura didara lọ.

128. Nitorina emi kà gbogbo ẹkọ́ rẹ si otitọ patapata: emi si korira gbogbo ọ̀na eke.

129. Iyanu li ẹri rẹ: nitorina li ọkàn mi ṣe pa wọn mọ́.

130. Ifihan ọ̀rọ rẹ funni ni imọlẹ; o si fi oye fun awọn òpe.

131. Emi yà ẹnu mi, emi mí hẹlẹ: nitori ti ọkàn mi fà si aṣẹ rẹ.

132. Iwọ bojuwò mi; ki o si ṣãnu fun mi, gẹgẹ bi iṣe rẹ si awọn ti o fẹ orukọ rẹ.

133. Fi iṣisẹ mi mulẹ ninu ọ̀rọ rẹ: ki o má si jẹ ki ẹ̀ṣẹkẹṣẹ ki o jọba lori mi.

134. Gbà mi lọwọ inilara enia; bẹ̃li emi o si ma pa ẹkọ́ rẹ mọ́.

135. Ṣe oju rẹ ki o mọlẹ si iranṣẹ rẹ lara; ki o si kọ mi ni ilana rẹ.

136. Odò omi ṣàn silẹ li oju mi nitori nwọn kò pa ofin rẹ mọ́.

O. Daf 119