115. Kuro lọdọ mi, ẹnyin oluṣe-buburu: emi o si pa ofin Ọlọrun mi mọ́.
116. Gbé mi soke gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ, ki emi ki o le yè: ki o má si jẹ ki oju ireti mi ki o tì mi.
117. Gbé mi soke, emi o si wà li ailewu: emi o si juba ìlana rẹ nigbagbogbo.
118. Iwọ ti tẹ̀ gbogbo awọn ti o ṣina kuro ninu ilana rẹ mọlẹ: nitori pe ẹ̀tan ni ironu wọn.
119. Iwọ ṣá gbogbo awọn enia buburu aiye tì bi ìdarọ́: nitorina emi fẹ ẹri rẹ.
120. Ara mi warìri nitori ìbẹru rẹ; emi si bẹ̀ru idajọ rẹ.