O. Daf 119:11-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Ọ̀rọ rẹ ni mo pamọ́ li aiya mi, ki emi ki o má ba ṣẹ̀ si ọ.

12. Olubukún ni iwọ, Oluwa: kọ́ mi ni ilana rẹ.

13. Ẹnu mi li emi fi nsọ gbogbo idajọ ẹnu rẹ.

14. Emi ti nyọ̀ li ọ̀na ẹri rẹ, bi lori oniruru ọrọ̀.

15. Emi o ma ṣe àṣaro ninu ẹkọ́ rẹ emi o si ma juba ọ̀na rẹ.

16. Emi o ma ṣe inu-didùn ninu ilana rẹ: emi kì yio gbagbe ọ̀rọ rẹ.

17. Fi ọ̀pọlọpọ ba iranṣẹ rẹ ṣe, ki emi ki o le wà lãye, ki emi ki o le ma pa ọ̀rọ rẹ mọ́.

18. Là mi li oju, ki emi ki o le ma wò ohun iyanu wọnni lati inu ofin rẹ.

19. Alejo li emi li aiye: máṣe pa àṣẹ rẹ mọ́ fun mi.

O. Daf 119