O. Daf 112:1-4 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ẹ ma yìn Oluwa. Ibukún ni fun ẹniti o bẹ̀ru Oluwa, ti inu rẹ̀ dùn jọjọ sí ofin rẹ̀.

2. Iru-ọmọ rẹ̀ yio lagbara li aiye: iran ẹni-diduro-ṣinṣin li a o bukún fun.

3. Ọlà ati ọrọ̀ yio wà ni ile rẹ̀: ododo rẹ̀ si duro lailai.

4. Fun ẹni-diduro-ṣinṣin ni imọlẹ mọ́ li òkunkun: olore-ọfẹ, o si kún fun ãnu, o si ṣe olododo.

O. Daf 112