1. MÁṢE pa ẹnu rẹ mọ́, Ọlọrun iyìn mi;
2. Nitori ti ẹnu awọn enia buburu, ati ẹnu awọn ẹlẹtan yà silẹ si mi: nwọn ti fi ahọn eke sọ̀rọ si mi.
3. Nwọn si fi ọ̀rọ irira yi mi ka kiri; nwọn si mba mi ja li ainidi.
4. Nipo ifẹ mi nwọn nṣe ọta mi: ṣugbọn emi ngba adura.
5. Nwọn si fi ibi san ire fun mi, ati irira fun ifẹ mi.
6. Yan enia buburu tì i: jẹ ki Olufisùn ki o duro li ọwọ ọtún rẹ̀.
7. Nigbati a o ṣe idajọ rẹ̀, ki a da a lẹbi: ki adura rẹ̀ ki o di ẹ̀ṣẹ;
8. Ki ọjọ rẹ̀ ki o kuru; ki ẹlomiran ki o rọpo iṣẹ rẹ̀.
9. Ki awọn ọmọ rẹ̀ ki o di alainibaba, ki aya rẹ̀ ki o di opó.
10. Jẹ ki awọn ọmọ rẹ̀ ki o di alarinkiri, ti nṣagbe: ki nwọn ki o ma tọrọ onjẹ jina si ibi ahoro wọn.
11. Jẹ ki alọnilọwọ-gbà ki o mu ohun gbogbo ti o ni; ki alejo ki o kó èrè iṣẹ́ rẹ̀ lọ.