O. Daf 105:1-4 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa? ẹ pè orukọ rẹ̀: ẹ fi iṣẹ rẹ̀ hàn ninu awọn enia.

2. Ẹ kọrin si i, ẹ kọ orin mimọ́ si i: ẹ ma sọ̀rọ iṣẹ iyanu rẹ̀ gbogbo.

3. Ẹ ma ṣogo li orukọ rẹ̀ mimọ́; jẹ ki aiya awọn ti nwá Oluwa ki o yọ̀.

4. Ẹ ma wá Oluwa ati ipá rẹ̀: ẹ ma wá oju rẹ̀ nigbagbogbo.

O. Daf 105