O. Daf 101:5-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Ẹnikẹni ti o ba nsọ̀rọ ẹnikeji rẹ̀ lẹhin, on li emi o ke kuro: ẹniti o ni ìwo giga ati igberaga aiya, on li emi kì yio jẹ fun.

6. Oju mi yio wà lara awọn olõtọ, ki nwọn ki o le ma ba mi gbe: ẹniti o ba nrìn li ọ̀na pipé, on ni o ma sìn mi.

7. Ẹniti o ba nṣe ẹ̀tan, kì o gbe inu ile mi: ẹniti o ba nsẹke kì yio duro niwaju mi.

8. Lojojumọ li emi o ma run gbogbo enia buburu ilẹ na; ki emi ki o le ke gbogbo oluṣe buburu kuro ni ilu Oluwa.

O. Daf 101