Num 5:28-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

28. Bi obinrin na kò ba si ṣe ẹni ibàjẹ́, ṣugbọn ti o mọ́; njẹ yio yege, yio si lóyun.

29. Eyi li ofin owú, nigbati obinrin kan ba yapa, labẹ ọkọ rẹ̀, ti o si di ẹni ibàjẹ́;

30. Tabi nigbati ẹmi owú ba dé si ọkọ kan, ti o ba si njowú obinrin rẹ̀; nigbana yio mu obinrin na duro niwaju OLUWA, ki alufa ki o si ṣe gbogbo ofin yi si i.

31. Nigbana li ọkunrin na yio bọ́ kuro ninu aiṣedede, obinrin na yio si rù aiṣedede ara rẹ̀.

Num 5