39. Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ ani titi di ẹni ãdọta ọdún, gbogbo ẹniti o wọ̀ inu iṣẹ-ìsin na, fun iṣẹ ninu agọ́ ajọ,
40. Ani awọn ti a kà ninu wọn, nipa idile wọn, gẹgẹ bi ile baba wọn, jẹ́ ẹgbẹtala o le ọgbọ̀n.
41. Wọnyi li awọn ti a kà ni idile awọn ọmọ Gerṣoni, gbogbo awọn ti o ṣe iṣẹ-ìsin ninu agọ́ ajọ, ti Mose ati Aaroni kà gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA.
42. Awọn ti a si kà ni idile awọn ọmọ Merari, nipa idile wọn, gẹgẹ bi ile baba wọn,
43. Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, ani titi di ẹni ãdọta ọdún, gbogbo ẹniti o wọ̀ inu iṣẹ-ìsin na, fun iṣẹ ninu agọ́ ajọ,
44. Ani awọn ti a kà ninu wọn nipa idile wọn jẹ́ ẹgbẹrindilogun.
45. Wọnyi li awọn ti a kà ninu idile awọn ọmọ Merari, ti Mose ati Aaroni kà gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA nipa ọwọ́ Mose.