3. Bi a ba si gbé wọn niyawo fun ẹnikan ninu awọn ọmọkunrin ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli miran, nigbana ni a o gbà ilẹ-iní wọn kuro ninu ilẹ-iní awọn baba wa, a o si fi kún ilẹ-iní ẹ̀ya ti a gbé wọn si: bẹ̃li a o si gbà a kuro ninu ipín ilẹ-iní ti wa.
4. Ati nigbati ọdún jubeli awọn ọmọ Israeli ba dé, nigbana li a o fi ilẹ-iní wọn kún ilẹ-iní ẹ̀ya ti a gbé wọn si: bẹ̃li a o si gbà ilẹ-iní wọn kuro ninu ilẹ-iní ẹ̀ya awọn baba wa.
5. Mose si paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli gẹgẹ bi ọ̀rọ OLUWA, pe, Ẹ̀ya awọn ọmọ Josefu fọ̀ rere.
6. Eyi li ohun ti OLUWA palaṣẹ nipa ti awọn ọmọbinrin Selofehadi, wipe, Ki nwọn ki o ṣe aya ẹniti o wù wọn; kiki pe, ninu idile ẹ̀ya baba wọn ni ki nwọn ki o gbeyawo si.
7. Bẹ̃ni ilẹ-iní awọn ọmọ Israeli ki yio yi lati ẹ̀ya de ẹ̀ya: nitori ki olukuluku awọn ọmọ Israeli ki o le faramọ́ ilẹ-iní ẹ̀ya awọn baba rẹ̀: