30. Nwọn si ṣí kuro ni Haṣmona, nwọn si dó si Moserotu.
31. Nwọn si ṣí kuro ni Moserotu, nwọn si dó si Bene-jaakani.
32. Nwọn si ṣí kuro ni Bene-jaakani, nwọn si dó si Hori-haggidgadi.
33. Nwọn si ṣí kuro ni Hori-haggidgadi, nwọn si dó si Jotbata.
34. Nwọn si ṣí kuro ni Jotbata, nwọn si dó si Abrona.
35. Nwọn si ṣí kuro ni Abrona, nwọn si dó si Esion-geberi.
36. Nwọn si ṣí kuro ni Esion-geberi, nwọn si dó si aginjù Sini, (ti ṣe Kadeṣi),
37. Nwọn si ṣí kuro ni Kadeṣi, nwọn si dó si òke Hori, leti ilẹ Edomu.
38. Aaroni alufa si gùn òke Hori lọ nipa aṣẹ OLUWA, o si kú nibẹ̀, li ogoji ọdún lẹhin ti awọn ọmọ Israeli ti ilẹ Egipti jade wá, li ọjọ́ kini oṣù karun.