Num 26:50-53 Yorùbá Bibeli (YCE)

50. Wọnyi ni idile ti Naftali gẹgẹ bi idile wọn: awọn ti a si kà ninu wọn jẹ́ ẹgba mejilelogun o le egbeje.

51. Wọnyi li a kà ninu awọn ọmọ Israeli, ọgbọ̀n ọkẹ, o le ẹgbẹsan o din ãdọrin.

52. OLUWA si sọ fun Mose pe,

53. Fun awọn wọnyi ni ki a pín ilẹ na ni iní gẹgẹ bi iye orukọ.

Num 26