19. Awọn ọmọ Juda, ni Eri ati Onani: ati Eri ati Onani kú ni ilẹ Kenaani.
20. Ati awọn ọmọ Juda gẹgẹ bi idile wọn; ti Ṣela, idile Ṣela: ti Peresi, idile Peresi: ti Sera, idile Sera.
21. Awọn ọmọ Peresi; ti Hesroni, idile Hesroni: ti Hamulu, idile Hamulu.
22. Wọnyi ni idile Juda gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn, nwọn jẹ́ ẹgba mejidilogoji o le ẹdẹgbẹta.
23. Awọn ọmọ Issakari gẹgẹ bi idile wọn: ti Tola, idile Tola: ti Pufa, idile Pufa:
24. Ti Jaṣubu, idile Jaṣubu: ti Ṣimroni, idile Ṣimroni.
25. Wọnyi ni idile Issakari gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn, nwọn jẹ́ ẹgba mejilelọgbọ̀n o le ọdunrun.