18. Edomu yio si di iní, Seiri pẹlu yio si di iní, fun awọn ọtá rẹ̀; Israeli yio si ṣe iṣe-agbara.
19. Lati inu Jakobu li ẹniti yio ní ijọba yio ti jade wá, yio si run ẹniti o kù ninu ilunla.
20. Nigbati o si wò Amaleki, o si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, Amaleki ni ekini ninu awọn orilẹ-ède; ṣugbọn igbẹhin rẹ̀ ni ki o ṣegbé.
21. O si wò awọn ara Keni, o si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, Agbara ni ibujoko rẹ̀, iwọ si tẹ́ itẹ́ rẹ sinu okuta.
22. Ṣugbọn a o run awọn ara Keni, titi awọn ara Aṣṣuri yio kó o lọ ni igbekùn.
23. O si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, A, tani yio wà, nigbati Ọlọrun yio ṣe eyi!
24. Awọn ọkọ̀ yio ti ebute Kittimu wá, nwọn o si pọn Aṣṣuri loju, nwọn o si pọn Eberi loju, on pẹlu yio si ṣegbé.
25. Balaamu si dide, o si lọ o si pada si ibujoko rẹ̀; Balaki pẹlu si ba ọ̀na rẹ̀ lọ.