8. O si wi fun wọn pe, Ẹ wọ̀ nihin li alẹ yi, emi o si mú ọ̀rọ pada tọ̀ nyin wá, bi OLUWA yio ti sọ fun mi: awọn ijoye Moabu si wọ̀ sọdọ Balaamu.
9. Ọlọrun si tọ̀ Balaamu wá, o si wipe, Awọn ọkunrin wo ni wọnyi lọdọ rẹ?
10. Balaamu si wi fun Ọlọrun pe, Balaki ọmọ Sippori, ọba Moabu, li o ranṣẹ si mi pe,
11. Kiyesi i, awọn enia kan ti ilẹ Egipti jade wá, ti o bò oju ilẹ: wá nisisiyi, fi wọn bú fun mi; bọya emi o le bá wọn jà, emi a si lé wọn lọ.
12. Ọlọrun si wi fun Balaamu pe, Iwọ kò gbọdọ bá wọn lọ; iwọ kò gbọdọ fi awọn enia na bú: nitoripe ẹni ibukún ni nwọn.
13. Balaamu si dide li owurọ̀, o si wi fun awọn ijoye Balaki pe, Ẹ ma ba ti nyin lọ si ilẹ nyin: nitoriti OLUWA kọ̀ lati jẹ ki mbá nyin lọ.
14. Awọn ijoye Moabu si dide, nwọn si tọ̀ Balaki lọ, nwọn si wipe, Balaamu kọ̀ lati bá wa wá.