1. OLUWA si sọ fun Aaroni pe, Iwọ ati awọn ọmọ rẹ, ati ile baba rẹ pẹlu rẹ, ni yio ma rù ẹ̀ṣẹ ibi-mimọ́: ati iwọ ati awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ ni yio ma rù ẹ̀ṣẹ iṣẹ-alufa nyin.
2. Ati awọn arakunrin rẹ pẹlu, ẹ̀ya Lefi, ẹ̀ya baba rẹ, ni ki o múwa pẹlu rẹ, ki nwọn ki o le dàpọ pẹlu rẹ, ki nwọn ki o ma ṣe iranṣẹ fun ọ: ṣugbọn iwọ ati awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ ni yio ma ṣe iranṣẹ niwaju agọ́ ẹrí.
3. Ki nwọn ki o ma pa aṣẹ rẹ mọ́, ki nwọn ki o si ma ṣe itọju gbogbo agọ́, kìki pe nwọn kò gbọdọ sunmọ ohun-èlo ibi-mimọ́ ati pẹpẹ, ki ati awọn, ati ẹnyin pẹlu ki o má ba kú.
4. Ki nwọn ki o si dàpọ pẹlu rẹ, ki nwọn ki o si ma ṣe itọju agọ́ ajọ, gẹgẹ bi gbogbo iṣẹ-ìsin agọ́: alejò kan kò sí gbọdọ sunmọ ọdọ nyin.
5. Ki ẹnyin ki o si ma ṣe itọju ibi-mimọ́, ati itọju pẹpẹ: ki ibinu ki o má ba sí mọ́ lori awọn ọmọ Israeli.
6. Ati emi, kiyesi i, mo ti mú awọn arakunrin nyin, awọn ọmọ Lefi kuro ninu awọn ọmọ Israeli: ẹnyin li a fi wọn fun bi ẹ̀bun fun OLUWA, lati ma ṣe iṣẹ-ìsin agọ́ ajọ.
7. Iwọ ati awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ ni yio si ma ṣe itọju iṣẹ-alufa nyin niti ohun gbogbo ti iṣe ti pẹpẹ, ati ti inu aṣọ-ikele: ẹnyin o si ma sìn: emi ti fi iṣẹ-alufa nyin fun nyin, bi iṣẹ-ìsin ẹ̀bun: alejò ti o ba si sunmọtosi li a o pa.
8. OLUWA si sọ fun Aaroni pe, Kiyesi i, emi si ti fi itọju ẹbọ igbesọsoke mi fun ọ pẹlu, ani gbogbo ohun mimọ́ awọn ọmọ Israeli, iwọ li emi fi wọn fun ni ipín, ati fun awọn ọmọ rẹ, bi ipín lailai.