15. Mose si binu gidigidi, o si wi fun OLUWA pe, Máṣe kà ẹbọ wọn si: emi kò gbà kẹtẹkẹtẹ kan lọwọ wọn, bẹ̃li emi kò pa ẹnikan wọn lara.
16. Mose wi fun Kora pe, Ki iwọ ati gbogbo ẹgbẹ rẹ ki o wá siwaju OLUWA, iwọ, ati awọn, ati Aaroni li ọla:
17. Ki olukuluku wọn ki o mú awo-turari rẹ̀, ki ẹ si fi turari sinu wọn, ki olukuluku nyin ki o mú awo-turari rẹ̀ wá siwaju OLUWA, ãdọtalerugba awo-turari; iwọ pẹlu ati Aaroni, olukuluku awo-turari rẹ̀.
18. Olukuluku wọn si mú awo-turari rẹ̀, nwọn si fi iná sinu wọn, nwọn si fi turari lé ori wọn, nwọn si duro li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, pẹlu Mose ati Aaroni.
19. Kora si kó gbogbo ijọ enia jọ si wọn si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ: ogo OLUWA si hàn si gbogbo ijọ enia na.
20. OLUWA si sọ fun Mose ati Aaroni pe,
21. Ẹ yà ara nyin kuro lãrin ijọ yi, ki emi ki o run wọn ni iṣéju kan.
22. Nwọn si doju wọn bolẹ, nwọn wipe, Ọlọrun, Ọlọrun ẹmi gbogbo enia, ọkunrin kan ha le ṣẹ̀, ki iwọ ki o si binu si gbogbo ijọ?
23. OLUWA si sọ fun Mose pe,
24. Sọ fun ijọ pe, Ẹ gòke wá kuro ni sakani agọ́ Kora, Datani, ati Abiramu.
25. Mose si dide, o si tọ̀ Datani ati Abiramu lọ; awọn àgba Israeli si tẹle e.
26. O si sọ fun ijọ pe, Mo bẹ̀ nyin, ẹ kuro ni ibi agọ́ awọn ọkunrin buburu yi, ẹ má si ṣe fọwọkàn ohun kan ti iṣe ti wọn, ki ẹ má ba run ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ wọn.
27. Bẹ̃ni nwọn si gòke lọ kuro nibi agọ́ Kora, Datani ati Abiramu, ni ìha gbogbo: Datani ati Abiramu si jade, nwọn si duro li ẹnu-ọ̀na agọ́ wọn, ati awọn aya wọn, ati awọn ọmọ wọn ọkunrin, ati awọn ọmọ wọn wẹ́wẹ.
28. Mose si wipe, Nipa eyi li ẹnyin o mọ̀ pe OLUWA li o rán mi lati ṣe gbogbo iṣẹ wọnyi; ati pe emi kò ṣe wọn lati inu ara mi wá.