14. Pẹlupẹlu iwọ kò ti imú wa dé ilẹ kan ti nṣàn fun warà ati fun oyin, bẹ̃ni iwọ kò fun wa ni iní ilẹ ati ọgba-àjara: iwọ o yọ oju awọn ọkunrin wọnyi bi? awa ki yio gòke wá.
15. Mose si binu gidigidi, o si wi fun OLUWA pe, Máṣe kà ẹbọ wọn si: emi kò gbà kẹtẹkẹtẹ kan lọwọ wọn, bẹ̃li emi kò pa ẹnikan wọn lara.
16. Mose wi fun Kora pe, Ki iwọ ati gbogbo ẹgbẹ rẹ ki o wá siwaju OLUWA, iwọ, ati awọn, ati Aaroni li ọla:
17. Ki olukuluku wọn ki o mú awo-turari rẹ̀, ki ẹ si fi turari sinu wọn, ki olukuluku nyin ki o mú awo-turari rẹ̀ wá siwaju OLUWA, ãdọtalerugba awo-turari; iwọ pẹlu ati Aaroni, olukuluku awo-turari rẹ̀.
18. Olukuluku wọn si mú awo-turari rẹ̀, nwọn si fi iná sinu wọn, nwọn si fi turari lé ori wọn, nwọn si duro li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, pẹlu Mose ati Aaroni.
19. Kora si kó gbogbo ijọ enia jọ si wọn si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ: ogo OLUWA si hàn si gbogbo ijọ enia na.
20. OLUWA si sọ fun Mose ati Aaroni pe,
21. Ẹ yà ara nyin kuro lãrin ijọ yi, ki emi ki o run wọn ni iṣéju kan.
22. Nwọn si doju wọn bolẹ, nwọn wipe, Ọlọrun, Ọlọrun ẹmi gbogbo enia, ọkunrin kan ha le ṣẹ̀, ki iwọ ki o si binu si gbogbo ijọ?
23. OLUWA si sọ fun Mose pe,