17. Mose si rán wọn lọ ṣe amí ilẹ Kenaani, o si wi fun wọn pe, Ẹ gbà ọ̀na ìha gusù yi, ki ẹ sì lọ sori òke nì.
18. Ki ẹnyin si wò ilẹ na, bi o ti ri; ati awọn enia ti ngbé inu rẹ̀, bi nwọn ṣe alagbara tabi alailagbara, bi diẹ ni nwọn, tabi pupọ̀;
19. Ati bi ilẹ na ti nwọn ngbé ti ri, bi didara ni bi buburu ni; ati bi ilu ti nwọn ngbé ti ri, bi ninu agọ́ ni, tabi ninu ilu odi;
20. Ati bi ilẹ na ti ri, bi ẹlẹtu ni tabi bi aṣalẹ̀, bi igi ba mbẹ ninu rẹ̀, tabi kò sí. Ki ẹnyin ki o si mu ọkàn le, ki ẹnyin si mú ninu eso ilẹ na wá. Njẹ ìgba na jẹ́ akokò pipọn akọ́so àjara.