Num 11:22-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

22. Agbo-ẹran tabi ọwọ́-ẹran ni ki a pa fun wọn, lati tó fun wọn ni? tabi gbogbo ẹja okun li a o kójọ fun wọn lati tó fun wọn?

23. OLUWA si sọ fun Mose pe, Ọwọ́ OLUWA ha kúru bi? iwọ o ri i nisisiyi bi ọ̀rọ mi yio ṣẹ si ọ, tabi bi ki yio ṣẹ.

24. Mose si jade lọ, o si sọ ọ̀rọ OLUWA fun awọn enia: o si pe ãdọrin ọkunrin ninu awọn àgba enia jọ, o si mu wọn duro yi agọ́ ká.

25. OLUWA si sọkalẹ wá ninu awọsanma, o si bá a sọ̀rọ, o si mú ninu ẹmi ti o wà lara rẹ̀, o si fi i sara awọn ãdọrin àgba na: o si ṣe, nigbati ẹmi na bà lé wọn, nwọn sì sọtẹlẹ ṣugbọn nwọn kò ṣe bẹ̃ mọ́.

26. Ṣugbọn o kù meji ninu awọn ọkunrin na ni ibudó, orukọ ekini a ma jẹ́ Eldadi, orukọ ekeji Medadi: ẹmi na si bà lé wọn; nwọn si mbẹ ninu awọn ti a kà, ṣugbọn nwọn kò jade lọ si agọ́: nwọn si nsọtẹlẹ ni ibudó.

27. Ọmọkunrin kan si súre, o si sọ fun Mose, o si wipe, Eldadi ati Medadi nsọtẹlẹ ni ibudó.

28. Joṣua ọmọ Nuni, iranṣẹ Mose, ọkan ninu awọn ọmọkunrin rẹ̀ dahùn, o si wipe, Mose oluwa mi, dá wọn lẹkun.

29. Mose si wi fun u pe, Iwọ njowú nitori mi? gbogbo enia OLUWA iba le jẹ́ wolĩ, ki OLUWA ki o fi ẹmi rẹ̀ si wọn lara!

30. Mose si lọ si ibudó, on ati awọn àgba Israeli.

31. Afẹfẹ kan si ti ọdọ OLUWA jade lọ, o si mú aparò lati okun wá, o si dà wọn si ibudó, bi ìwọn ìrin ijọ́ kan ni ìha ihin, ati bi ìwọn ìrin ijọ́ kan ni ìha ọhún yi ibudó ká, ni ìwọn igbọnwọ meji lori ilẹ.

Num 11