48. Nitoripe OLUWA ti sọ fun Mose pe,
49. Kìki ẹ̀ya Lefi ni ki iwọ ki o máṣe kà, bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe kà iye wọn mọ́ awọn ọmọ Israeli.
50. Ṣugbọn ki iwọ ki o yàn awọn ọmọ Lefi sori agọ́ érí, ati sori gbogbo ohun-èlo rẹ̀, ati sori ohun gbogbo ti iṣe tirẹ̀: awọn ni ki o ma rù agọ́, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀; awọn ni yio si ma ṣe iṣẹ-ìsin rẹ̀, ki nwọn ki o si dó yi agọ́ na ká.
51. Nigbati agọ́ na ba si ṣí siwaju, ki awọn ọmọ Lefi ki o tú u palẹ: nigbati nwọn o ba si pa agọ́ na, awọn ọmọ Lefi ni ki o gbé e duro: alejó ti o ba sunmọtosi, pipa ni.
52. Ki awọn ọmọ Israeli ki o si pa agọ́ wọn, olukuluku ni ibudó rẹ̀, ati olukuluku lẹba ọpagun rẹ̀, gẹgẹ bi ogun wọn.