38. Awọn ọmọ Senaah ẹgbãji o di ãdọrin.
39. Awọn alufa: awọn ọmọ Jedaiah ti ile Jeṣua, ẹgbã o di mẹtadilọgbọn.
40. Awọn ọmọ Immeri, ẹgbẹrun o le mejilelãdọta.
41. Awọn ọmọ Paṣuri, ẹgbẹfa o le mẹtadiladọta.
42. Awọn ọmọ Harimu ẹgbẹrun o le mẹtadilogun.
43. Awọn ọmọ Lefi: awọn ọmọ Jeṣua, ti Kadmieli, ninu ọmọ Hodafa, mẹrinlelãdọrin.
44. Awọn akọrin: awọn ọmọ Asafu, mejidilãdọjọ.
45. Awọn oludena: awọn ọmọ Ṣallumu, awọn ọmọ Ateri, awọn ọmọ Talmoni, awọn ọmọ Akkubu, awọn ọmọ Hatita, awọn ọmọ Ṣobai, mejidilogoje.