Neh 7:34-39 Yorùbá Bibeli (YCE)

34. Awọn ọmọ Elamu miran ẹgbẹfa o le mẹrinlelãdọta.

35. Awọn ọmọ Harimu, ọrindinirinwo.

36. Awọn ọmọ Jeriko, ọtadinirinwo o le marun.

37. Awọn ọmọ Lodi, Hadidi, ati Ono, ọrindilẹgbẹrin o le ọkan.

38. Awọn ọmọ Senaah ẹgbãji o di ãdọrin.

39. Awọn alufa: awọn ọmọ Jedaiah ti ile Jeṣua, ẹgbã o di mẹtadilọgbọn.

Neh 7