Neh 7:29-40 Yorùbá Bibeli (YCE)

29. Awọn ọkunrin Kiriat-jearimu, Kefira, ati Beeroti, ọtadilẹgbẹrin o le mẹta,

30. Awọn ọkunrin Rama ati Gaba, ẹgbẹta o le mọkanlelogun.

31. Awọn ọkunrin Mikmasi, mejilelọgọfa.

32. Awọn ọkunrin Beteli ati Ai, mẹtalelọgọfa.

33. Awọn ọkunrin Nebo miran mejilelãdọta.

34. Awọn ọmọ Elamu miran ẹgbẹfa o le mẹrinlelãdọta.

35. Awọn ọmọ Harimu, ọrindinirinwo.

36. Awọn ọmọ Jeriko, ọtadinirinwo o le marun.

37. Awọn ọmọ Lodi, Hadidi, ati Ono, ọrindilẹgbẹrin o le ọkan.

38. Awọn ọmọ Senaah ẹgbãji o di ãdọrin.

39. Awọn alufa: awọn ọmọ Jedaiah ti ile Jeṣua, ẹgbã o di mẹtadilọgbọn.

40. Awọn ọmọ Immeri, ẹgbẹrun o le mejilelãdọta.

Neh 7