Neh 7:19-33 Yorùbá Bibeli (YCE)

19. Awọn ọmọ Bigfai, ẹgbã o le mẹtadilãdọrin.

20. Awọn ọmọ Adini, ãdọtalelẹgbẹta o le marun.

21. Awọn ọmọ Ateri, ti Hesekiah mejidilọgọrun.

22. Awọn ọmọ Haṣamu, ọrindinirinwo o le mẹjọ.

23. Awọn ọmọ Besai, ọrindinirinwo o le mẹrin.

24. Awọn ọmọ Harifu mejilelãdọfa.

25. Awọn ọmọ Gibioni, marundilọgọrun.

26. Awọn ọkunrin Betlehemu ati Netofa, ọgọsan o le mẹjọ.

27. Awọn ọkunrin Anatoti, mejidilãdoje.

28. Awọn ọkunrin Bet-asmafeti, mejilelogoji.

29. Awọn ọkunrin Kiriat-jearimu, Kefira, ati Beeroti, ọtadilẹgbẹrin o le mẹta,

30. Awọn ọkunrin Rama ati Gaba, ẹgbẹta o le mọkanlelogun.

31. Awọn ọkunrin Mikmasi, mejilelọgọfa.

32. Awọn ọkunrin Beteli ati Ai, mẹtalelọgọfa.

33. Awọn ọkunrin Nebo miran mejilelãdọta.

Neh 7