10. Emi pẹlu, ati awọn arakunrin mi, ati awọn ọmọkunrin mi, nyá wọn ni owó ati ọkà, ẹ jẹ ki a pa èlé gbígbà yí tì.
11. Mo bẹ̀ nyin, ẹ fi oko wọn, ọgbà-ajarà wọn, ọgbà-olifi wọn, ati ile wọn, ida-ọgọrun owo na pẹlu, ati ti ọkà, ọti-waini, ati ororo wọn, ti ẹ fi agbara gbà, fun wọn padà loni yi.
12. Nwọn si wipe, Awa o fi fun wọn pada, awa kì yio si bere nkankan lọwọ wọn; bẹ̃li awa o ṣe bi iwọ ti wi. Nigbana ni mo pe awọn alufa, mo si mu wọn bura pe, nwọn o ṣe gẹgẹ bi ileri yi.
13. Mo si gbọ̀n apo aṣọ mi, mo si wipe, Bayi ni ki Ọlọrun ki o gbọ̀n olukuluku enia kuro ni ile rẹ̀, ati kuro ninu iṣẹ rẹ̀, ti kò mu ileri yi ṣẹ, ani bayi ni ki a gbọ̀n ọ kuro, ki o si di ofo. Gbogbo ijọ si wipe, Amin! nwọn si fi iyìn fun Oluwa. Awọn enia na si ṣe gẹgẹ bi ileri yi.