14. Ẹnu-bode ãtàn ni Malkiah ọmọ Rekabu, ijòye apa kan Bet-hakkeremu tun ṣe; o kọ́ ọ, o gbe ilẹkùn rẹ̀ ro, àgadágodo rẹ̀ ati itìkun rẹ̀.
15. Ṣallumu, ọmọ Kol-hose, ijòye apakan Mispa si tun ẹnu-bode orisun ṣe; o kọ́ ọ, o si bò o, o si gbe ilẹkùn rẹ̀ ro, àgadágodo rẹ̀, ati itìkun rẹ̀ ati odi adagun Ṣiloa li ẹ̀ba ọgba ọba, ati titi de atẹ̀gun ti o sọkalẹ lati ile Dafidi lọ.
16. Lẹhin rẹ̀ ni Nehemiah, ọmọ Asbuku, ijòye idaji Bet-huri, tun ṣe titi de ibi ọkánkán iboji Dafidi, ati de adagun ti a ṣe, ati titi de ile awọn alagbara.