Neh 11:15-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Ninu awọn ọmọ Lefi pẹlu: Ṣemaiah, ọmọ Haṣubu, ọmọ Asrikamu, ọmọ Haṣabiah, ọmọ Bunni;

16. Ati Ṣabbetai ati Josabadi, ninu olori awọn ọmọ Lefi ni alabojuto iṣẹ ode ile Ọlọrun.

17. Ati Mattaniah ọmọ Mika, ọmọ Sabdi, ọmọ Asafu, ni olori lati bẹ̀rẹ idupẹ ninu adura: ati Bakbukiah ẹnikeji ninu awọn arakunrin rẹ̀, ati Abda ọmọ Ṣammua, ọmọ Galali, ọmọ Jedutuni.

18. Gbogbo awọn ọmọ Lefi ninu ilu mimọ́ jẹ ọrinlugba o le mẹrin.

19. Ati awọn adèna, Akkubu, Talmoni, ati awọn arakunrin wọn ti nṣọ ẹnu ọ̀na jẹ mejilelãdọsan.

Neh 11