Mat 7:22-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

22. Ọpọlọpọ enia ni yio wi fun mi li ọjọ na pe, Oluwa, Oluwa, awa ko ha sọtẹlẹ li orukọ rẹ? ati orukọ rẹ ki a fi lé awọn ẹmi èṣu jade? ati li orukọ rẹ ki a fi ṣe ọ̀pọ iṣẹ iyanu nla?

23. Nigbana li emi o si wi fun wọn pe, Emi kò mọ̀ nyin ri, ẹ kuro lọdọ mi, ẹnyin oniṣẹ ẹ̀ṣẹ.

24. Nitorina ẹnikẹni ti o ba gbọ́ ọ̀rọ temi wọnyi, ti o ba si ṣe wọn, emi o fi wé ọlọ́gbọn enia kan, ti o kọ́ ile rẹ̀ si ori àpata:

25. Òjo si rọ̀, ikún omi si dé, afẹfẹ si fẹ́ nwọn si bìlu ile na; ko si wó, nitoriti a fi ipilẹ rẹ̀ sọlẹ lori àpata.

26. Ẹnikẹni ti o ba si gbọ́ ọ̀rọ temi wọnyi, ti kò si ṣe wọn, on li emi o fi wé aṣiwere enia kan ti o kọ́ ile rẹ̀ si ori iyanrin:

27. Òjo si rọ̀, ikún omi si de, afẹfẹ si fẹ́, nwọn si bìlu ile na, o si wó; iwó rẹ̀ si pọ̀ jọjọ.

28. Nigbati o si ṣe ti Jesu pari gbogbo òrọ wọnyi tan, ẹnu yà gbogbo enia si ẹkọ́ rẹ̀:

29. Nitori o nkọ́ wọn bi ẹniti o li aṣẹ, ki si iṣe bi awọn akọwe.

Mat 7