Mat 20:22-30 Yorùbá Bibeli (YCE)

22. Ṣugbọn Jesu dahùn, o si wipe, Ẹnyin ko mọ̀ ohun ti ẹnyin mbère. Ẹnyin le mu ninu ago ti emi ó mu, ati ki a fi baptismu ti a o fi baptisi mi baptisi nyin? Nwọn wi fun u pe, Awa le ṣe e.

23. O si wi fun wọn pe, Lõtọ li ẹnyin o mu ninu ago mi, ati ninu baptismu ti a o fi baptisi mi li a o si fi baptisi nyin; ṣugbọn lati joko li ọwọ́ ọtún ati li ọwọ́ òsi mi, ki iṣe ti emi lati fi funni, bikoṣepe fun kìki awọn ẹniti a ti pèse rẹ̀ silẹ fun lati ọdọ Baba mi wá.

24. Nigbati awọn mẹwa iyokù gbọ́ ọ, nwọn binu si awọn arakunrin wọn mejeji.

25. Ṣugbọn Jesu pè wọn sọdọ rẹ̀, o si wipe, Ẹnyin mọ̀ pe awọn ọba Keferi a ma lò agbara lori wọn, ati awọn ẹni-nla ninu wọn a ma fi ọlá tẹri wọn ba.

26. Ṣugbọn kì yio ri bẹ̃ lãrin nyin: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fẹ pọ̀ ninu nyin, ẹ jẹ ki o ṣe iranṣẹ nyin;

27. Ati ẹnikẹni ti o ba fẹ ṣe olori ninu nyin, jẹ ki o ma ṣe ọmọ-ọdọ nyin:

28. Ani gẹgẹ bi Ọmọ-enia kò ti wá ki a ṣe iranṣẹ fun u, bikoṣe lati ṣe iranṣẹ funni, ati lati fi ẹmi rẹ̀ ṣe iràpada ọpọlọpọ enia.

29. Bi nwọn ti nti Jeriko jade, ọ̀pọ enia tọ̀ ọ lẹhin.

30. Si kiyesi i, awọn ọkunrin afọju meji joko leti ọ̀na, nigbati nwọn gbọ́ pe Jesu nrekọja, nwọn kigbe soke, wipe, Oluwa, iwọ Ọmọ Dafidi, ṣãnu fun wa.

Mat 20