12. Nitori ẹnyin ti sọ ọ di aimọ́, ninu eyi ti ẹ wipe, Tabili Oluwa di aimọ́; ati eso rẹ̀, ani onjẹ rẹ̀ ni ohun ẹ̀gan.
13. Ẹnyin wi pẹlu pe, Wo o agara kili eyi! ẹnyin ṣitìmú si i, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; ẹnyin si mu eyi ti o ya, ati arọ, ati olokunrùn wá; bayi li ẹnyin mu ọrẹ wá: emi o ha gbà eyi lọwọ nyin? li Oluwa wi.
14. Ṣugbọn ifibu ni fun ẹlẹtàn na, ti o ni akọ ninu ọwọ́-ẹran rẹ̀, ti o si ṣe ileri ti o si fi ohun abùku rubọ si Oluwa; nitori Ọba nla li emi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, ẹ̀ru si li orukọ mi lãrin awọn keferi.