36. O si mu ọmọ kekere kan, o fi i sarin wọn; nigbati o si gbé e si apa rẹ̀, o wi fun wọn pe,
37. Ẹnikẹni ti o ba gbà ọkan ninu iru awọn ọmọ kekere wọnyi li orukọ mi, o gbà mi: ẹnikẹni ti o ba si gbà mi, ki iṣe emi li o gbà, ṣugbọn o gbà ẹniti o rán mi.
38. Johanu si da a lohùn, o wipe, Olukọni, awa ri ẹnikan nfi orukọ rẹ lé awọn ẹmi èṣu jade, on kò si tọ̀ wa lẹhin: awa si da a lẹkun, nitoriti ko tọ̀ wa lẹhin:
39. Jesu si wipe, Ẹ máṣe da a lẹkun mọ́: nitori kò si ẹnikan ti yio ṣe iṣẹ agbara li orukọ mi, ti o si le yara sọ ibi si mi.
40. Nitori ẹniti ko ba kọ oju ija si wa, o wà ni iha tiwa.