Mak 2:12-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. O si dide lojukanna, o si gbé akete na, o si jade lọ li oju gbogbo wọn; tobẹ̃ ti ẹnu fi yà gbogbo wọn, nwọn si yìn Ọlọrun logo, wipe, Awa ko ri irú eyi rí.

13. O si tún jade lọ si eti okun; gbogbo ijọ enia si wá sọdọ rẹ̀, o si kọ́ wọn.

14. Bi o si ti nkọja lọ, o ri Lefi ọmọ Alfeu, o joko ni bode, o si wi fun u pe, Mã tọ̀ mi lẹhin. O si dide, o tọ̀ ọ lẹhin.

15. O si ṣe, bi o si ti joko tì onjẹ ni ile rẹ̀, ọ̀pọ awọn agbowode ati ẹlẹṣẹ wá bá Jesu joko pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀: nitoriti nwọn pọ̀ nwọn si tọ̀ ọ lẹhin.

16. Nigbati awọn akọwe ati awọn Farisi si ri i ti o mbá awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ jẹun, nwọn wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẽtiri ti o fi mba awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ jẹ, ti o si mba wọn mu?

17. Nigbati Jesu gbọ́, o wi fun wọn pe, Awọn ti ara wọn le kì iwá oniṣegun, bikoṣe awọn ti ara wọn ko da: Emi ko wá lati pè awọn olododo, bikoṣe awọn ẹlẹṣẹ si ironupiwada.

Mak 2