Mak 13:9-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Ṣugbọn ẹ mã kiyesara nyin: nitori nwọn ó si fi nyin le awọn igbimọ lọwọ; a o si lù nyin ninu sinagogu: a o si mu nyin duro niwaju awọn balẹ ati awọn ọba nitori orukọ mi, fun ẹrí si wọn.

10. A kò le ṣaima kọ́ wasu ihinrere ni gbogbo orilẹ-ède.

11. Ṣugbọn nigbati nwọn ba nfà nyin, lọ, ti nwọn ba si nfi nyin le wọn lọwọ, ẹ maṣe ṣaniyan ṣaju ohun ti ẹ o sọ; ṣugbọn ohun ti a ba fifun nyin ni wakati na, on ni ki ẹnyin ki o wi: nitori kì iṣe ẹnyin ni nwi, bikoṣe Ẹmí Mimọ́.

12. Arakunrin yio si fi arakunrin fun pipa, ati baba yio fi ọmọ rẹ̀ hàn; awọn ọmọ yio si dide si obi wọn, nwọn o si mu ki a pa wọn.

13. Gbogbo enia ni yio si korira nyin nitori orukọ mi: ṣugbọn ẹniti o ba foritì i titi fi de opin, on na li a o gbalà.

14. Ṣugbọn nigbati ẹnyin ba ri irira isọdahoro nì, ti o duro nibiti ko tọ́, ti a ti ẹnu woli Danieli ṣọ, (ẹnikẹni ti o ba kà a, ki o yé e,) nigbana ni ki awọn ti mbẹ ni Judea sálọ si ori òke:

15. Ki ẹniti mbẹ lori ile ki o máṣe sọkalẹ lọ sinu ile, bẹ̃ni ki o má si ṣe wọ̀ inu rẹ̀, lati mu ohunkohun jade ninu ile rẹ̀:

16. Ati ki ẹniti mbẹ li oko ki o maṣe pada sẹhin wá lati mu aṣọ rẹ̀.

17. Ṣugbọn egbé ni fun awọn ti o lóyun, ati fun awọn ti o nfi ọmu fun ọmọ mu li ọjọ wọnni!

18. Ki ẹ si ma gbadura, ki sisá nyin ki o máṣe bọ́ si igba otutù.

Mak 13