8. Awọn mejeji a si di ara kan: nitorina nwọn kì iṣe meji mọ́, bikoṣe ara kan.
9. Nitorina ohun ti Ọlọrun ba so ṣọkan, ki enia ki o máṣe yà wọn.
10. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si tun bi i lẽre ọ̀ran kanna ninu ile.
11. O si wi fun wọn pe, Ẹnikẹni ti o ba fi aya rẹ̀ silẹ, ti o ba si gbé omiran ni iyawo, o ṣe panṣaga si i.
12. Bi obinrin kan ba si fi ọkọ rẹ̀ silẹ, ti a ba si gbé e ni iyawo fun ẹlomiran, o ṣe panṣaga.
13. Nwọn si gbé awọn ọmọ-ọwọ tọ̀ ọ wá, ki o le fi ọwọ́ tọ́ wọn: awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si ba awọn ti o gbé wọn wá wi.
14. Ṣugbọn nigbati Jesu ri i, inu bi i, o si wi fun wọn pe, Ẹ jẹ ki awọn ọmọ kekere ki o wá sọdọ mi, ẹ má si ṣe da wọn lẹkun: nitoriti irú wọn ni ijọba Ọlọrun.