39. Ẹ wò ọwọ́ mi ati ẹsẹ mi, pe emi tikarami ni: ẹ dì mi mu ki ẹ wò o; nitoriti iwin kò li ẹran on egungun lara, bi ẹnyin ti ri ti mo ni.
40. Nigbati o si wi bẹ̃ tán, o fi ọwọ́ on ẹsẹ rẹ̀ hàn wọn.
41. Nigbati nwọn kò si tí igbagbọ́ fun ayọ̀, ati fun iyanu, o wi fun wọn pe, Ẹnyin ni ohunkohun jijẹ nihinyi?
42. Nwọn si fun u li ẹja bibu, ati afára oyin diẹ.
43. O si gba a, o jẹ ẹ loju wọn.
44. O si wi fun wọn pe, Nwọnyi li ọrọ ti mo sọ fun nyin, nigbati emi ti wà pẹlu nyin pe, A kò le ṣe alaimu ohun gbogbo ṣẹ, ti a ti kọ ninu ofin Mose, ati ninu iwe awọn woli, ati ninu Psalmu, nipasẹ̀ mi.